ÀWỌN ÀMÌ ÀTI ÌTỌ́JÚ ÀÀRÙN JẸJẸRẸ Ọ̀NÀ TÍ Ó LỌ SÍ ILÉ-ỌMỌ (CERVICAL CANCER) – Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀

Play episode
Hosted by
John Olatunji

 

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àmì kankan lè má f’arahàn, ṣùgbón bí ó bá ti ń wọra síi, àwọn àmì wọ̀nyi yíò máa je jáde;

Àkọ́kọ́; Tí ìbálòpọ̀ bá ńdun obìrin.

Ìkejì; Tí ẹ̀jẹ̀ bá ńti ojú-ara jáde l’êhìn ìbálòpọ̀.

Ìkẹ́ta; Rírí ẹ̀jẹ̀ l’ěhìn tí obìrin ti parí nkan oṣù rẹ̀, kí àkókò nkan oṣù míràn tó bẹ̀rẹ̀.

Ìkẹ́rin; Kí obìrin tí kò ṣe nkan oṣù mọ́, tí ó ti wọ àkókò menopause, tún dédé bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ẹ̀jẹ̀.

Ìkarùnun; Rírí ẹ̀jẹ̀ l’átojú ara, kí ẹ̀jẹ̀ náà sì máa rùn.

Ó ṣe pàtàkì láti ṣe àyẹ̀wò fún ààrùn yí l’ọ́dọdún gégébí àlejò wa, Dr. Oluwabunmi Aiyegbusi ti ṣe gbà wá ní iyànjú lórí ètò Jígí. Nítorí àwọn àmì wọ̀nyí kìí tètè jẹ yọ, àyàfi bí ààrùn náà bá ti ń wọra bọ̀.

Fún ìtọ́jú tàbí ọ̀nà àbáyọ nípa tí ààrùn yí:

Òtítọ́ tí ó wà nípa ààrùn jẹjẹrẹ ni wípé ìrètí yíò wá láti rí ìtọ́jú tí ó fi ni l’ọ́kàn balẹ̀ gbà nígbàtí a bá tètè ṣe àyẹ̀wò láti mọ̀ wípé ó wà l’agọ́ ara.

Onírúurú ìtọ́jú tí ó wà fún ààrùn yí ni ìwọ̀nyí;

Ìkíní

Iṣẹ́ abẹ; eléyìí pín sí ipa mẹta;

Láti fi iṣẹ́ abẹ gbé cell tí ó tí ní Jẹjẹrẹ ní ọ̀nà sí ilé ọmọ (cervix) kúrò.

Láti fi iṣẹ́ abẹ gbé gbogbo ọ̀nà sí ilé ọmọ kúrò pátápátá.

Láti fi iṣẹ́ abẹ gbé ọ̀nà sí ilé ọmọ (cervix) àti ilé ọmọ pàápàá (uterus) kúrò nítorí jẹjẹrẹ náà ti gbilẹ̀, kí ó má bàá ṣe jàmbá ju bí ó ti wà lọ.

Ìkejì

Radiotherapy: Èyí ni títan iná sí ojú ibití jẹjẹrẹ náà wà, iná yẹn yíò pa àwọn cell tí ó ti ní àkóràn.

Ìkẹta

Chemotherapy: Èyí ni láti lo oògùn tí yíò pa àwọn cell tí ó ní Jẹjẹrẹ, yálà nípa abẹ́rẹ́ nínú omi tí wọ́n fà sí àgọ́ ara (drip) tàbí nípa oògùn lílò.

Ìkẹrin

Immunotherapy: Èyí jẹ́ ìtọ́jú nípa oògùn lílò láti kọ ojú ìjà sí jẹjẹrẹ. Oògùn náà yíò fún àwon ọlọ́pàá ààbò ní àgọ ara (immune system) ní okun tí ó pé’ye.

Ìkarùnún

Supportive Care: Èyí ni ṣíṣe ìtọ́jú àwọn tí ó ní ààrùn náà nípa fífún wọn ní oògùn tí yíò dín ìrora wọn kù. Ìrora máa ńpọ̀ l’ápọ̀jù fún àwọn tí ó ní ààrùn jẹjẹrẹ. Fún ìdí èyí, ni àfikún sí oògún tí ó wà fún ìtọ́jú jẹjẹrẹ, wọn a tún fún wọn l’óògùn tí yíò dín ìrora wọn kù.

Àyèwò ní ìgbà dé ìgbà jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti dènà ààrùn jẹjẹrẹ ojú ọ̀nà sí ilé ọmọ.

Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀ ni atọ́kùn ètò Jígí lórí Rédíò Ìróidùnnú, ẹ tẹ́tí sí ètò náà l’álalẹ́ẹ ọjọ́ ẹtì ní agogo mẹ́jọ alẹ́, lórí ẹ̀rọ ayélujára www.iroidunnu.com.

 

 

Join the discussion

More from this show

Iroidunnu

Subscribe

Episode 5