KÍNI ÒFIN ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ SỌ NÍPA BÍ A TI ŃṢE ÌGBÉYÀWÓ?

Play episode
Hosted by
John Olatunji

KÍNI ÒFIN ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ SỌ NÍPA BÍ A TI ŃṢE ÌGBÉYÀWÓ?

Ní àìpẹ́ yí ní ìròyìn kan gbòde kan nípa ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìlú Èkó tí ó sọ wípé gbogbo ìgbéyàwó tí àwọn ènìyàn ṣe ní ìlú Ìkòyí ti di òtúbántẹ́. Ọ̀rọ̀ yí dá rògbòdìyàn sílẹ̀ kí àwọn aṣojú ìjọba tó jáde láti ṣàlàyé wípé ọ̀rọ̀ náà kò ríbẹ́ẹ̀ àti wípé ọ̀rọ̀ náà sì wà ní ilé ẹjọ́.

Láti dáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí àwọn ènìyàn ń béèrè nípa ìṣopọ̀ tí ó b’ófin mu ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọ̀jọ̀gbọ́n Túnjí Ajíbọ́lá ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lórí ètò Ìdá Òfin, èyí tí o máa n wáyé ní agogo mẹ́jọ àbọ̀ òròwúrọ̀ ọjọjọ́ Àbámẹ́ta lórí Rédíò Ìróidùnnú.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Túnjí nínú àlàyé wọn sọ wípé ìgbéyàwó tí ilé ẹjọ́ fọwọ́sí, èyí tí a mọ̀ sí court marriage jẹ́ ìlànà ìgbéyàwó ti orílẹ-èdè Bìrìtìkó mú wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbàtí a wà ní abẹ́ ìsìnrú wọn, èyí sì jẹ́ àjèjì sí àṣà àti ìṣe wa.

Wọ́n tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé wípé, ìgbéyàwó tí ó tọ́nà jù ni ti ìbílẹ̀ wa, èyí tí a ti ń san owó ìdána àti ádùrá awọn òbí, bí o tilẹ jẹ́ wípé kòì tí sí ìwé ẹ̀rí fún èyí.

Ní àkótán, wọ́n gba ijọba ní ìmọ̀ràn láti ṣètò bí àwọn tọkọtaya yíò ṣe leè máa rí ìwé ẹ̀rí gbà fún ìgbéyàwó tí wọ́n bá ṣe lọ́nà ìbílẹ̀ àti wípé kí àwọn tí wọn bá ṣe ìgbéyàwó wọn lọ́nà ìbílẹ̀ má ṣe f’òya rárá, nitoripe tí wọ́n bá ti leè pèsè ẹlẹri meji láti jẹrìí sí àsopọ wọn lọ́nà ìbílẹ̀, ìgbéyàwó náà yíò dúró ní ibikíbi tí wọ́n bá lọ, èyí ni ohun tí òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó.

Fún ìmọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ nípa òfin, ẹ leè kàn sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Túnjí Ajíbọ́lá lórí nọ́mbà yí; 08066123141

 

Join the discussion

More from this show

Iroidunnu

Subscribe

Episode 7