KÍNÍ OHUN Tí Ó Ń FÀÁ Tí Ọ̀PỌ̀ ÌPINNU ỌDÚN TUNTUN FI MÁA Ń KÙNÀ? (WHY DO MOST NEW YEAR RESOLUTIONS FAIL?) – Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀

Play episode
Hosted by
John Olatunji

 

 

KÍNÍ OHUN Tí Ó Ń FÀÁ Tí Ọ̀PỌ̀ ÌPINNU ỌDÚN TUNTUN FI MÁA Ń KÙNÀ? (WHY DO MOST NEW YEAR RESOLUTIONS FAIL?) – Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀

 

 

Ìpinnu fún ọdún tuntun jẹ́ àṣà tí ó wọ́pọ̀ lóde òní, ṣùgbón ìrírí àti ìwádìí ti fihàn wípé, ọ̀pọ̀ àwọn ìpinnu wọ̀nyí kìí di mímú ṣẹ. Bí ọdún yí ti nlọ sí òpin, ìrètí wà wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò tún gbìyànjú láti ṣe ìpinnu tuntun, yálà lórí ọ̀rọ̀ ìṣúná owó, ìlera, àyípadà àwọn ìwà abárakú, ìbáṣepọ̀ tí ó múná dóko, iṣẹ́, òwò, ìtẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́, ìhà sí ẹ̀sìn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Láti leè dènà ìkùnà àwọn ìpinnu fún ọdún tuntun tí ó ńbọ̀ yí ni èmi Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀ tí mo jẹ́ atọ́kùn ètò Jígí lórí Rédíò Ìróidùnnú fi ṣe ìwádí sí ohun tí ohun fàá tí ọ̀pọ̀ àwọn ìpinnu wọ̀nyí fi ń kùnà.

Ìjábọ̀ ìwádìí mi yíò wá bí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè méjì wọ̀nyí;

Àkọ́kọ́; Ǹjẹ́ ìpinnu ní kò gbé ìwọ̀n tó ni tàbí ẹni tí ó ṣe ìpinnu ni ó ní wàhálà tí ó fi ń forísánpọ́n?

Ìwádìí mi fi hàn gbangba wípé wàhálà kò sí pẹ̀lú àwọn ìpinnu ṣùgbón ọwọ ẹni tí ó ṣe ìpinnu ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún fì sí jùlọ, nitori wípé ìpinnu kò leè tayọ ènìyàn tí ó ṣeé àti wípé ó rọrùn fún ẹnikẹ́ni láti ṣe ìpinnu ohun tí ó dára fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ńkùnà ni à ti fi ìpinnu sí ojú ìṣe.

Ọlọrun ẹlẹ́dàá ti fún ènìyàn ní ọgbọ̀n, òye ati ipá láti mú èròngbà rere rẹ̀ ṣe, sùgbón ó wà kú s’ọ́wọ́ọ ẹni tí ó ṣe ìpinnu láti ṣiṣẹ́ ríi wípé ìfojúsùn àti àbá òhun di mímú ṣẹ.

Èkejì; Kíni àwọn ohun tí o leè ṣe láti mú ìpinnu rẹ ṣe?

Ohun Àkọ́kọ́; Jẹ́ olótìítọ́ sí ara rẹ àti ohun tí o ti pinnu rẹ̀. Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ẹnu rẹ̀ sọ ohunkohun tí ó fẹ́ ṣe tàbí jẹ́, sùgbọ́n láì ṣe wípé ọkàn àti ẹnu bá ṣọ̀kan kò leè sí ìmúṣẹ irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.

 

Ohun Èkejì; Ṣetán fún àyípadà pẹ̀lú ara rẹ.

O gbúdọ̀ ṣetán láti yí padà nínú èrò, ìwà, ìrìn àti ìṣe rẹ kí o tó leè mú ìpinnu rẹ̀ tuntun ṣe. Ìrírí àti àṣeyọrí ènìyàn kò leè yàtọ̀ sí irú ẹni tí ènìyàn jẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ láti ṣe ohun tuntun gbúdọ̀ kọ́kọ́ gbìyànjú láti di tuntun nínú ìgbé ayé rẹ̀.

Ohun Ìkẹ́ta; Yẹ ọ̀rẹ́ rẹ wò. Ìwà jọ̀’wà ni wọ́n ń pè ní ọ̀rẹ́ jọ̀’rẹ́, ẹni a pè l’ólè kò sì gbọdọ̀ tún máa gbé ọmọ ẹran jó. Ẹni tí ó fẹ́ láti s’íwọ́ ọtín mímu kò gbọdọ̀ yan ilé ọtín mímu láàyò tàbí jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ọlọ́tín àmupara. Ìgbésí ayé ènìyàn kò leè ṣe bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn tí ó bá yíi ká. Fi àwọn ènìyàn tí o fẹ́ láti fi ìwà àti ìgbé ayé rẹ jọ yí ara rẹ ká.

Ohun Ìkẹ́rin; Ní ìgbàgbọ́ nínú ara rẹ. Kò sí ẹni tí yíò gbà ọ́ gbọ́ bí o kò bá gba ara rẹ gbọ́. O gbọ́dọ̀ máa fi èyí hàn nínú ọ̀rọ̀ sísọ sí ara rẹ. Máa ṣọ fún ara rẹ wípé o leè ṣe ní abẹ́ àkóso bí ó ti wù kí ó rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò gbìyànjú láti fi ohun gbogbo ṣú ọ, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ rẹ gbúdọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ.

Ohun Ìkárunun; Jẹ́ kí àwọn ànfààní, ẹwà àti iyì tí ó wà nínú ìmúṣẹ ìpinnu àti ìfojúsùn rẹ máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ ìwúrí fún àwọn ìgbésẹ rẹ l’ójojúmọ́ títí tí ìpinnu rẹ náà yíò fi di mímú ṣẹ. Nígbàkúgbà tí ọkàn rẹ bá fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì, jẹ́ kí àwọn ohun tí yíò jẹ́ bí èrè ìmúṣẹ rẹ jẹ́ amóríyá fún ọ láti tèsíwájú.

Nípa ṣíṣe àwọn nkan wọ̀nyí, ìdánilójú wà wípé ìpinnu rẹ fún ọdún tuntun leè di mímú ṣẹ.

 

Orukọ mi ni Olúwakẹ́mi Akíntáyọ̀, ẹ̀ máa tẹ́tí sí mi lórí Rédíò Ìróidùnnú ní Ọjọjọ́ Ọjọ́rú ni Agogo Mẹ́san Alẹ́ fún ètò OBÌRIN NI MÍ àti ní Ọjọjọ́ Ẹtì ni Agogo Mẹ́jọ fún ètò JÍGÍ.

Ẹ leè kàn sí mi lóríi 08035835925

 

 

 

Join the discussion

More from this show

Iroidunnu

Subscribe

Episode 1