MÁ ṢE GBA Ẹ̀MÍ ARA RẸ!

Play episode
Hosted by
John Olatunji

MÁ ṢE GBA Ẹ̀MÍ ARA RẸ!

Dáwọ́ dúró, má gbẹ̀mí ara rẹ
Bèrè fún ìrànwọ́
Nítòótọ̀ ọ̀pọ̀ ti leè já ọ kulẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe dẹ́kun àti máa béèrè
Ìrànlọ́wọ́ rẹ leè má wá níbití o rokàn sí
Ìwọ sáà ti máa béèrè
Ọkàn rẹ pòrúurùu, ìbànújẹ́ gba ọkàn rẹ
ẹ̀gàn àti ìtìjú bò ọ̀ mọ́lẹ̀
Ohun èyí o wù kí ayé ì báà múwá sí èrò àti ọ̀nà rẹ, béèrè ìrànwọ́, béèrè lọwọ Ọlọrun, sì tún bèèrè lọ́wọ́ ènìyàn
Ọ̀pọ̀ leè já ọ kulẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú ìrànwọ́ yíò dé
Gbígba ẹ̀mí ara ẹni kọ́ lọ́nà àbáyọ
Ikú ojo, ẹ̀sín àti ìfiré ni ìgbẹ̀mí ara ẹni
Ẹni tí o fún ọ ní ẹ̀mí ní ètò àti ìpinnu fún ayé rẹ
Ìkùnà nlá ni ìgbẹ̀mì ara ẹni
Ohun tó le nbọ̀ wá dẹ̀rọ̀, bo ti wù kòpẹ̀ tó
Má pa ara rẹ nítorí ohun tí ìwọ kò ní, máa rántí wípé àwọn kan ní gbogbo rẹ̀ sùgbọ́n tí wọn kò sí mímọ láti gbádùn rẹ
Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri ìmọ́lẹ̀ yíò tàn
Kò sí ohun tí o le tí kò ní dẹ̀rọ̀
o tóbi ju àṣìṣe rẹ lọ, nitoripe o ní agbára láti ṣe àtúnṣe
Má ṣe wo aago alaago ṣiṣe, ìpín ò pa pọ̀, àyànmọ́ ò dọ́gba
Má ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ, kò lérè fún ìwọ, àwọn tó fẹ ọ àti ẹlẹdàá rẹ
Pariwo, ké tan tan, béèrè fún ìrànwọ́ lọ́wọ́ ẹni mímọ̀ àti àjèjì.
Ayọ̀ rẹ ti dé tán, má ṣe gbẹ̀mí ara rẹ.

Join the discussion

More from this show

Iroidunnu

Subscribe

Episode 2